Bismillahir Rahmanir Rahim

 

TANI ENI TI ANPE  NI MIRZA GHULAM QADIANI ?

Eyin olukawe wa owonjulo !

Asaju wa ojise nla Muhammad (SAW) ni Akehinde gbgban ninu awon ojise ninu eto Olohun, Oba to fi AL-Qur’an mimo ranse ni iwe ofin igbehin ti Oba adeda se ni imona aiye raiye fun gbogbo agbanla aiye. Awa ti a je ijo Anabi Muhammad (SAW) ni Olohun fi ebun pataki yi dalola. Asi gba awon iro idunu nipa orire ayinipekun yi pelu toka gbolohun Olohun ti nso bayi wipe :

« Oni, ni emi olohun se asepe esin yin fun yin, mo si se asepe idera mi fun yin, mo si yonu si esin Islam ni esin ododo fun yin » (Qur’an 5 : 3)

 

Inigbagbo ododo si opin ise riran, opin iranse ati asepe esin won, owun  ni iyato to nbe larin ijo musulumi ati awon elesin omiran, owon si ni idena atako fun gbogbo adadale ti ogbon ori ati awon afikun ti awon ijo odale parapo ngbe yo si agbaiye esin Islam lojiji ni idakokan. Al-Qur’an ati awon tira hadiths ati sira ati awon iwe itan ati awon iwe esin miran parapo jeri wipe Akehinde gbegban ni ojise nla Muhammad (SAW) lati odo Olohun. Eyi lo fi nye wa wipe oluwa ti ka ofin esin pe fun wa osi se Al-Qur’an ni iwe ofin ise reran igbehin ko le ma je imona fun gbogbo agbaiye. Oluwa nso bayi ninu Al-Qu’ran iwe mimo : « Muhammad ki-i se baba okankan ninu awon omokunrin yin sugbon ojise Oluwa ati Akehinde gbegban ninu awon ojise ni-i-se, Oluhun ni oba Alamotan » (Qu’ran 33 : 40)

 

Ojise nla Muhammad (SAW) so bayi wipe : « Ni ododo igbe ojise dide ati iranse ti dopin, nipa bee ojise kankan Anabi kankan ki yio wa lehin mi » (Tirmidhi vol 2 p. 5, Musnad Ahmed) 

 

Gbogbo awon ojise to saju ni won fun iro idunu nipa dide ojise tuntun ti-I se Anabi Muhammad (SAW) : « Ninu ijo mi ni ojulowo opuro meta yio ti jade, gbogbo eni kokan ninu won yio ma perare ni ojise oluhun, sugban emi

ni Akehinde gbegban ninu awon Anabi Olohun, ojise kankan koni wa lehin mi … » (Abou Daud, Tirmidhi).                 

 

Jamat Ahmadiyya ati Atako ti won doju re ko ije iranse Olohun ti Anabi Muhammad (SAW).  Ninu awon oniruru ijo alatako to doju ko esin islam ninu oriran riran akoko ni odun egberu kan le logorun merin (1400 ans). Lehin igbati Anabi Muhammad se Hijirath, iyato ni ti ijo Ahmadiyya je. Oludasile ijo Ahmadiyya Mirza Ghulam se atako Al-Qur’an ati ojise nla Muhammad leniti npe Anabi Muhammad (SAW) ni opuro, o si ngbiyanju yi itumo Al-Qur’an pada lati le ma pa adapa iro sinu oro Olohun. Won nperawon ni Musulumi ododo fun araiye, awon iranse esu npepe soju ona anu. Won nfi lakaye awon oloju dudu alayimokan ninu awon musulumi agbaiye fi sere. Opolopo awon musulumi ni won mo awon ofin ati opo esin Islam, sugbon won ko funa si awon adadale ofin ati opo esin Islam, sugbon won ko fura si awon adadale ati afikun ti awon ijo Ahmadiyya fi bonu esin Islam. Die ninu awon enia lo mo wipe okunrin yi to bere si pe ipe gegebi ojise Olohun ati olugbeja esin Islam, omo lehin awon iran funfun (ijoba Britain) ti won dira fun gbe dide lati yo ife Anabi Muhammad (SAW) ojise Olohun kuro lokan awon musulumi atipe ki won fi le pana emi ijagun soju ona t’Olohun re leniti nfi pa adapa iro lati fi yi itumo Al-Qur’an pada beni nfi dogbon pin ijo esin Islam si ototo.

 

MIRZA GHULAM nperare ni ojise  Olohun ninu oro re to so bayi wipe : « Oku enia ni awon ti koni igbagbo si Akehinde ninu awon ojise. Ibukun ni fun enito gbami gbo, ninu gbogbo ona imolohun, emi ni ona ikehin, beni ninu gbogbo awon imole, emi ni imole ikehin, egbe ni fenito ba komi sile, lalayi kosi temi, okunkun ni gbogbo aiye » (Kishtee-e-Nooh, Roohani Khazain vol 19 p. 61)

 

Nida keji Mirza Ghulam nperare ni igba keji ojise nla Muhammad (SAW) leniti nfi yi oro Olohun pada, fi pa adapa iro bayi wipe : « Ojise Olohun ni Anabi Muhammad, awon omo lehin re je olulekoko mo awon keferi, won yio si ma ke arawon ». Mirza Ghulam ndun ara re ninu leniti nso

wipe : Olohun pe owun ni Muhammad o si pe owun ni ojise ninu oro yi (Roohani Khazain vol  18 p. 207).

 

«  Ninu gbogbo ona imolohun, emi ni ona ikehin atipe ninu gbogbo awon imole, emi ni imole ikehin. Egbe ni fun enito komi sile, bikosi ola mi okunkun ni gbogbo aiye ». (Kishtee-e-Nooh, Roohani Khazain vol 19 p. 61). 

 

Nigbati o je wipe emi ni atumbi ojise mimo, to si je wipe gbogbo ise ti Anabi Muhammad (SAW) je fun araiye nbe labe digi ibogi mi, bi oro ba ri bee tani okunrin naa ti nperare ni ojise olohun ninu igbesi aiye kan loto abi isemi to yato si tiwa ? (EK. Ghulti Ka Iala p. 8 : Roohani Khazain vol 18 p. 212).

 

« Emi nikansoso ni ayanfe Olohun to se ni ojise, ninu ijo yi. Oruko ojise yi ko to si enikankan, atipe oro asotele ni wipe enikan nbowa, igbe ojise dide ti dopin ». (Haqeeqatul-Wahi,  Roohani vol 22 p. 407)

 

« Nidi eyi o foju han wipe Mirza nji oruko Akehinde gbegban ninu awon Anabi Olohun ati awon ojise lodo Anabi Muhammad (SAW) o wa nperare bee. Lehin igba gboro, Mirza da ijo sile leyi to foju jo Islam o wa npe gbogbo awon musulumi ododo ni alayigbagbo keferi ». Mirza Ghulam nso bayi wipe : « Yato si awon omo ale esin Islam, awon ti okan won ko gba olohun gbo, awon apakan gbami gbo, won si momi ni ojise ». (Aina-e-Kamalat-e-Islam, Roohani Khazain vol 5 p. 547)

« Olohun so fun mi wipe gbogbo eniti ojise mi ba jise mi fun ti ko gbagbo ki-i se musulum ododo » (Iwe ti Mirza ko si Dr Abdoul-Hakeem).

 

Omo Mirza Bashir Ahmad so bayi wipe : « Gbogbo eniti nba ni igbagbo si Anabi Musa sugbon ti koni igbagbo si Anabi Issa abi koni igbagbo si Anabi Muhammad (SAW) sugbon koni igbagbo si Messia emi mimo ti a fun iro idunu nipa re, eleyi ki-i se keferi lasan sugbon onigberaga poki enia ni atipe ki-i se musulumi ododo » (Kalimatul-Fasl page 110, par Mirza Bashir Ahmad).

  

JAMAAT AHMADIYYA ATI AYIPADA ITUMO IWE MIMO

TI-I SE AL-QUR’AN          

Jamaat Ahmadiyya nse fari, iyanran, se karimi lori wipe won te Al-Qur’an jade si opolopo ede. Ogunlogo enia ko mo ero Mirza Ghulam ati awon Jamaat re wipe igbiyanju lati le yi itumo Al-Qur’an pada ni.

 

Awon ona ti won le gba yi itumo Al-Qur’an na pada ni won yi :

-         Iyi oro ti Olohun so pada

-         Ayipada ninu itumo ati alaye oro olohun ni ifosi wewe

-         Lilo oro Olohun si ona to lodi to yato si ohun ti olohun wi

-         Ipa awon ofin Al-Qur’an re

 

Gbogbo awon ona mererin won yi ni Mirza Ghulam Ahmad Qadiani mo dajudaju wipe owun gba Lodi soro olohun. 

 

Pelu wipe owo ayipada ko kan Al-Qur’an sugbon Mirza Ghulam Ahmad bere si yi itumo Al-Qur’an pada ati awon alaye re ni ekunrere to si nfife inu re gbona odi lo pupo ninu awon oro Olohun.

 

ONA  AYIPADA  ORO  OLOHUN

 

Ni ododo ayipada kosi fun Al-Qur’an ninu awon onte re ni ede Larubawa bena ni Jamaat Ahmadiyya ko yi onte Al-Qur’an pada, sugbon Mirza Ghulam Ahmad yi pupe ninu awon itumo oro Olohun pada-nigbatio nfi won se itoka ati awijare ninu awon re. Apejuwe melo kan nbe ninu iwe iroyin yi.

 

AYIPADA TO BA  ITUMO AL-QUR’AN ATI ALAYE NI EKUNRERE

 LATI OWO MIRZA GHULAM

Opolopo apejuwe lo nbe fun ayipada to ba itumo Al-Qur’an lati omo Mirza Ghulam. Eyi to pataki julo ninu won owun na ni Ayath 33 Surath 40 : « Muhammad ki-I se baba enikankan ninu awon omokunrin yin sugbon ojise

Olohun ni-i se ati Akehinde gbegban ninu awon ojise ati opin awon Anabi Olohun, Olohun ni Alamotan ».

 

Latara oro Olohun yi ati awon oro Anabi (Hadiths) gbogbo awon musulumi ododo ni won ti gbagbo wipe Akehinde gbegban ninu awon ojise Olohun ati opin ninu awon Anabi Olohun ni Anabi Muhammad je.

 

Sugbon e bere wo lodo enikeni ninu awon ijo Qadiyaniyya Ahmadiyya omo lehin Mirza Ghulam, iro kansoso atako kansoso na ni won yio fi fun yin

lesi wipe rara o! rara o! Anabi Muhammad (SAW) ki-I se Akehinde ati opin awon Anabi Olohun sugbon eni ami kan lo je fun awon ojise to nbo lojo iwaju. Sugbon lehin igbati o silekun ije Anabi Olohun fun nare, o tun tilekun naa leniti  nso bayi :

 

« Ibukun Olohun nbe fun enito dami mo ni ojise Olohun, ninu gbogbo awon ona imole Olohun, emi ni ona igbehin oriburuku ni feniti ko mo mi nitoripe lalayi kosi temi okunkun ni gbogbo aiye » (Roohani Khazain, vol 19 p. 61). 

 

Sugbon won koni esi kankan fun ibere yi : « Kini kati pe ti arakunrin ti nji oruko Akehinde gbegban ninu awon ojise Olohun lowo Anabi Muhammad ? »

Agara yio dawon tenu-tenu, oro yio pesi je, won yio si mawo bi oyaya.

 

ONA ODI TI AHMAD MIRZA GHULAM NGBA

LO AWON ORO AL-QUR’AN

 

Al-Qur’an kun fun kiki oro Olohun eyito fi nyin ayanfe re ti-i se Anabi Muhammad (SAW). Lapejuwe AL-Qur’an 9:33, 17:1, 3:31, 48:1-2, 36:1-3, 108:1, 21:107 titi lo bee.

 

Gbogbo won je awon ayaths to han wipe Olohun sawon lesa lati fi yin Anabi Muhammad (SAW).

 

Sibesibe, eka awon iwe Mirza Ghulam, ni adayanri Haqeeqatul wahi, vol 22, Roohani Khazai, e o ri wipe lati oju ewe 77 titi de 111 Mirza Ghulam nji awon oro Olohun fi se eri fi gberare ga wipe : owun ni Olohun ran nise ki-I se Anabi Muhammad ! Lapejuwe :

« Owun leniti o fi ojise re ranse si agbaiye pelu imona ati esin ododo lati le fi bori gbogbo awon esin atowoda, botile jewipe awon osebo ko gba » (As-saff 61 : 9) Tazkirah p. 338 ; iwe elekerin. 

‘’So wipe : ‘’ Bi eyin ba nferan Olohun ni ododo e tele mi, Olohun yo feran yin, yio si fori awon ese yin ji yin, oba olopolopo aforiji ati ike ni Olohun’’ (Aal-Imran 3 : 31) (Haqeeqatul wahi p. 82)

« Ki-i soro ife inu re bikose ise ti Olohun ba ran si-i »

(An-Nahin 53 : 3-4) (Tazkirah p. 378)

            ‘’Awon eniti won se adehun igbagbo ododo fun Olohun : owo Olohun leke owo won’’ (AL Fath 48 : 10) (Haqeeqatul-Wahi, 80)

‘’So wipe : ‘’Ni ododo eda enia gegebi tiyin ni eni naa ise ti a fi ran mi nipe ikansoso ni Olohun yin !’’ (Al-Kahf : 18 : 10) (Haqeequatul Wahi p. 81)

« Ni ododo dajudaju awa ti fun-un ni isegun to han gbangba, ki Olohun le fi se aforiji ohun ti oti siwaju ninu asise re ati eyiti o gbehin, ati ki o le se

asepe idera re le o lori ati ki o le to-o si oju ona ti o to tara » (AL-Muzammil 73 : 15) (Haqeeqatul Wahi p. 10).

            ‘’Dajudaju awa ti ran ojise kan si yin ti yio je olujeri leyin lori gegebi atise ran ojise kan si Firiaona’’.

            ‘’Dajudaju awa ti fun-un ni ore to po’’ (AL-Kawthar 108 : 1) (Haqeeqatul-Wahi p. 107) tazkirah p. 479.

            « Nidi eyi eyin ko pa won sugbon Olohun lo pawon, bee sini iwo koni o soko sugbon Olohun ni o soko » (AL-Anfal 8 : 17) (Haqeeqatul Wabi p. 70).

            « Ayath AL-Qur’an (17 : 1).  « Subhaana iladhi asraa bi abdihii lailan min al-Masjid al Haram ilaa al-Masjid al aqsa…. »

            ‘’Mimo ni fun eniti o mu olujosin re, eru re (Muhammad) rin l’oru ojo kan lati Mosalasi abowo (Haram) lo si Mosalasi ti o jina rere (aqsa) ti awa fi ibukun yinka re’’. Adapa iro Mirza Ghulam ni wipe itumo Mosalasi yi ni

Mosalasi ti baba towun ko ti owun si se atunse re. (Akojo awon ipolongo, Collection d’annonces vol 3 p. 286)

            Eyin na e ge e yewo ninu Lakaye yin ! lati awon ogorun odun to niye ni awon musulumi ko ronu si ona gba jagun lati gba Masjid AL-Asa (Saint Cité de Jerusalem).

Ninu adapa iro Mirza ghulam ni wipe Mosalasi Aqsa ni eyiti baba towun ko si Qadiani atipe Anabi Muhammad ko lo si Jerusalem ni oru laelatul-Is-rai sugbon Qadiani ni Anabi Muhammad lo si. Ki lo fi ndara to eyi

fun awon jew !

 

IPA OFIN AL-QUR’AN RE

            Gbolohun Jihad ninu esin Islam ntumo si ogun jija loju ona ti oto pelu awon idi oro to fese mule lati gba eto eni ninu re : igbogunti imunisin, igbat eto omo enia fun-un latile ma se emi ninu esin ati fifi ominira ati alafia joba lokan awon enia. Olohun so bayi wipe :

            « Ki e si ma bawon ja titi ti ki yio fi si idamu mo ti esin yio si wa (ni ominira) fun olohun »

            Sugbon bi won ba dekun (ija), nigbanaa ko gbodo si igbogunti ayafi si awon alabosi ». (Qur’an 2 : 193)

            « Ki e se ma pawon nibikibi ti owo yin ba tewon, ki e si le won jade nibiti won leyin jade ». (Qur’an 2 : 191)

            « Ati ki e si ma ba awon osebo ja patapata gegebi won ti se nba yin ja patapata, ki e si mo amodaju wipe Olohun nbe pelu awon olupaiya re » (Qur’an 9 : 36).

Pelu gbogbo awon itoka, awijare to daju lati odo Olohun si awon ojise re nipa ijagun si oju ona Olohun, Mirza Ghulam tun laiya lati se atako jihad (ijagun si oju ona olohun). Mirza Ghulam ko akosile bayi wipe :

« Lati igba odo mi titi oni, fun nkan bi odun marun le logota, ise pataki ti mo doju ko pelu ahan mi ati gege ikowe mi, owun naa ni iyi okan awon musulumi ododo losi ibi ife otito ati igbagbo ati ifokantan ijoba Britain ati ipa emi jihad re kuro lokan awon alayimokan ninu awon musulumi ». (Kitab-il-Bariyah, Roohani Khazain vol 13 p. 350).

 

« Fun anfani ijoba Britain egberu pona adota (50 000) iwe atoko ni mo te atejade re ti mo si pin si aarin ilu yi ati awon ile okere ati awon ilu miran ti je ilu esin Islam lati fi pa jihad re kuro ni lakaye awon musulumi ododo.

 

Abayori re ni wipe awon egbegberu pona egberu lona ogorun to po ninu awon musulumi ni won fi jihad sile » (Roohani Khazain vol 15 p. 114).

 

Awon ebu, elebu, ifi enu ete jeni ti Mirza Ghulam ndoju re ko Anabi Muhammad ati awon ona eru ti won ngba yi itu mo AL-Qur’an pada si ife inu arawon, owun lo je ki o han si gbogbo musulumi agbaiye wipe Mirza Ghulam ati ijo re ti-i se ijo Ahmadiyya won ki-i se musulumi ododo sugbon ojulowo alatako, ota to foju han pete pete ni won je fun esin Islam sibesibe won tun nperawon ni musulumi ododo, won nfi lakaye awon alayimokan ninu awon musulumi sere, ni adayanri ninu agbaiye AFRICA ni aye gbawon gidi lati le ma si awon oloju dudu alayimokan musulumi lona kuro loju ona esin Islam ti Anabi Muhammad (SAW) lo si ona anu, esin atowoda ti Islam Ahmad Mirza Ghulam.

 

Ki Olohun dakun jowo so gbogbo awon musulumi agbarijo aiye kuro ninu ona anu yi l’oruko esin Islam. Ki Olohun bawa safihan ete, ogbon ewe, iwa jamba ti Mirza Ghulam Qadiani fun awon alayimokan omo ijo re, nitoripe won ko mo ododo ipile awon akosile won yi. Amin.

           

Alafia Olohun ko ma be pelu gbogbo awon eniti ntona otito.

 

 

            Dr Seyd Rashid Ali

             P.O BOX : 11560

             Fax 971.9.2442846

                Dibba, Al-Fujairah

                   United Arab Emirates

                      E-mail : rasyed@emirates .net.ae